Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 8:20-29 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ní àkókò ìjọba Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì yan ọba fún ara wọn.

21. Nítorí náà, Jehoramu kó gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí Sairi láti bá Edomu jagun. Níbẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun Edomu ti yí wọn ká. Ní òru, òun ati àwọn olórí ogun rẹ̀ kọlu àwọn ará Edomu tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n sì sá àsálà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá pada sí ilé wọn.

22. Láti ìgbà náà ni Edomu ti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ Juda. Ní àkókò kan náà ni ìlú Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda.

23. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jehoramu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

24. Jehoramu kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Ahasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

25. Ní ọdún kejila tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli ni Ahasaya, ọmọ Jehoramu, jọba ní ilẹ̀ Juda.

26. Ẹni ọdún mejilelogun ni nígbà tí ó jọba ni Jerusalẹmu, ó sì jọba fún ọdún kan. Atalaya ni ìyá rẹ̀, ọmọ Omiri, ọba ilẹ̀ Israẹli.

27. Ọ̀nà ìdílé Ahabu ọba ni Ahasaya tẹ̀ sí, ó sì ṣe burúkú níwájú OLUWA, bí ìdílé Ahabu ti ṣe; nítorí pé àna ló jẹ́ fún Ahabu.

28. Ahasaya bá Joramu, ọba Israẹli lọ, wọ́n gbógun ti Hasaeli, ọba Siria, ní Ramoti Gileadi. Àwọn ọmọ ogun Siria ṣá ọba Joramu lọ́gbẹ́.

29. Ó pada sí ìlú Jesireeli, ó lọ wo ọgbẹ́ náà sàn. Ahasaya, ọba Juda, ọmọ Jehoramu, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 8