Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 25:5-19 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa Sedekaya, wọ́n bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì túká kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

6. Ọwọ́ wọn tẹ Sedekaya, wọ́n bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ó sì dá ẹjọ́ fún un.

7. Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni.

8. Ní ọjọ́ keje oṣù karun-un ọdún kọkandinlogun ìjọba Nebukadinesari, ọba Babiloni, Nebusaradani, tí ń ṣiṣẹ́ fún ọba Babiloni, tí ó sì tún jẹ́ olórí àwọn tí ń ṣọ́ Babiloni wá sí Jerusalẹmu.

9. Ó sun ilé OLUWA níná, ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn ilé ńláńlá tí ó wà níbẹ̀ ni ó sì dáná sun.

10. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea, tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.

11. Nebusaradani kó àwọn tí wọ́n kù láàrin ìlú ati àwọn tí wọ́n sá tọ ọba Babiloni lọ, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn yòókù lọ sí ìgbèkùn.

12. Ṣugbọn ó fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ láti máa tọ́jú ọgbà àjàrà ati láti máa dáko.

13. Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada bàbà ńlá tí ó wà ninu ilé OLUWA pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà wọn lọ sí Babiloni.

14. Wọ́n kó àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀kọ̀, àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná lẹ́nu àtùpà, àwọn àwo turari ati àwọn ohun èlò bàbà tí wọ́n máa ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.

15. Bákan náà, wọ́n kó àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwo kòtò, gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti wúrà ati fadaka, ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.

16. Bàbà tí Solomoni fi ṣe àwọn òpó mejeeji, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kọjá wíwọ̀n.

17. Gíga ọ̀kan ninu àwọn òpó náà jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, ọpọ́n idẹ tí ó wà lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta, wọ́n fi bàbà ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati pomegiranate yí ọpọ́n náà ká, òpó keji sì dàbí ti àkọ́kọ́ pẹlu ẹ̀wọ̀n bàbà náà.

18. Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraya olórí alufaa, ati Sefanaya igbákejì alufaa, ati àwọn aṣọ́nà mẹta.

19. Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 25