Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 25:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa ọdún kẹsan-an ìjọba rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ odi yí i ká.

2. Wọ́n dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya.

3. Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn náà mú láàrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́.

4. Nígbà náà ni wọ́n lu odi ìlú náà, ọba ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n lu odi ìlú náà, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin odi mejeeji lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, wọ́n sì gba ọ̀nà tí ó lọ sí Araba.

5. Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa Sedekaya, wọ́n bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì túká kúrò lẹ́yìn rẹ̀.

6. Ọwọ́ wọn tẹ Sedekaya, wọ́n bá mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ó sì dá ẹjọ́ fún un.

7. Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni Nebukadinesari ọba yọ ojú Sedekaya, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì mú un lọ sí Babiloni.

8. Ní ọjọ́ keje oṣù karun-un ọdún kọkandinlogun ìjọba Nebukadinesari, ọba Babiloni, Nebusaradani, tí ń ṣiṣẹ́ fún ọba Babiloni, tí ó sì tún jẹ́ olórí àwọn tí ń ṣọ́ Babiloni wá sí Jerusalẹmu.

9. Ó sun ilé OLUWA níná, ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu. Gbogbo àwọn ilé ńláńlá tí ó wà níbẹ̀ ni ó sì dáná sun.

10. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea, tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 25