Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 21:13-23 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó ní òun óo jẹ Jerusalẹmu níyà bí òun ti jẹ Samaria níyà. Ó ní bí òun ti ṣe sí ìdílé Ahabu ati àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun óo gbá àwọn eniyan náà kúrò ní Jerusalẹmu, bí àwo tí a nù tí a sì da ojú rẹ̀ bolẹ̀.

14. OLUWA ní òun óo kọ àwọn eniyan òun yòókù sílẹ̀, òun óo fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn, wọn yóo sì kó wọn lọ bí ìkógun.

15. Nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun burúkú lójú òun, wọ́n sì ti mú òun bínú láti ìgbà tí àwọn baba ńlá wọn ti kúrò ní Ijipti, àní títí di òní olónìí.”

16. Manase pa ọpọlọpọ àwọn eniyan aláìṣẹ̀ títí tí ẹ̀jẹ̀ fi ń ṣàn ní ìgboro Jerusalẹmu. Ó tún fa àwọn eniyan Juda sinu ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà; nípa bẹ́ẹ̀ ó mú kí wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA.

17. Gbogbo nǹkan yòókù tí Manase ṣe ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

18. Manase kú, wọ́n sì sin ín sinu ọgba Usa tí ó wà ní ààfin. Amoni ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

19. Ẹni ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún meji. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Meṣulemeti ọmọ Harusi ará Jotiba.

20. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA bí Manase, baba rẹ̀ ti ṣe.

21. Ó tẹ̀ sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, ó sì bọ àwọn ère tí baba rẹ̀ bọ.

22. Ó kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀, kò sì júbà àṣẹ rẹ̀.

23. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 21