Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 21:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hefisiba.

2. Manase ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn eniyan ilẹ̀ náà, tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

3. Ó tún àwọn ilé oriṣa tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti parun kọ́, ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún oriṣa Baali, ó sì gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, bí Ahabu, ọba Israẹli, ti gbẹ́ ẹ. Ó sì ń bọ àwọn ìràwọ̀.

4. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ oriṣa sinu ilé OLUWA, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti máa sin òun.

5. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún àwọn ìràwọ̀ ninu àwọn àgbàlá mejeeji tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA.

6. Ó fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, a máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn aláfọ̀ṣẹ, a sì máa ṣe àlúpàyídà. Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó hùwà tí ó burú gidigidi níwájú OLUWA, ó sì rú ibinu OLUWA sókè.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 21