Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 20:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. n óo sì jẹ́ kí ó gbé ọdún mẹẹdogun sí i. N óo gba òun ati Jerusalẹmu lọ́wọ́ ọba Asiria. N óo sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí tèmi fúnra mi ati nítorí ìlérí tí mo ṣe fún Dafidi, iranṣẹ mi.’ ”

7. Aisaya bá sọ fún àwọn iranṣẹ ọba pé kí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ sí orí oówo rẹ̀, kí ara rẹ̀ lè dá.

8. Hesekaya ọba bèèrè pé, “Kí ni yóo jẹ́ àmì pé OLUWA yóo wò mí sàn, ati pé n óo lọ sí ilé OLUWA ní ọjọ́ kẹta?”

9. Aisaya dáhùn pé, “OLUWA yóo fún ọ ní àmì láti fihàn pé òun yóo mú ìlérí òun ṣẹ. Èwo ni o fẹ́, ninu kí òjìji lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá tabi kí ó pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá?”

10. Hesekaya dáhùn pé, “Ó rọrùn fún òjìji láti lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá, kí ó pada sẹ́yìn ni mo fẹ́.”

11. Aisaya gbadura sí OLUWA, OLUWA sì mú kí òjìji pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá lára àtẹ̀gùn ilé tí ọba Ahasi ṣe.

12. Ní àkókò kan náà ni Merodaki Baladani, ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn ranṣẹ sí Hesekaya nítorí ó gbọ́ pé Hesekaya ń ṣe àìsàn.

13. Hesekaya gba àwọn oníṣẹ́ náà ní àlejò. Ó fi gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀, fadaka, wúrà, turari, òróró iyebíye ati gbogbo ohun ìjà rẹ̀ hàn wọ́n. Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra rẹ̀ ati ní gbogbo ìjọba rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n.

14. Nígbà náà ni wolii Aisaya lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekaya, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin wọnyi ti wá, kí ni wọ́n sì sọ fún ọ?”Hesekaya dáhùn pé, “Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, láti Babiloni.”

15. Aisaya bá tún bèèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ninu ààfin rẹ?”Ọba dáhùn, ó ní, “Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra tí n kò fi hàn wọ́n.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 20