Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 20:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò kan Hesekaya ṣàìsàn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ kú. Wolii Aisaya ọmọ Amosi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o palẹ̀ ilé rẹ mọ́ nítorí pé kíkú ni o óo kú, o kò ní yè.”

2. Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní,

3. “Mo bẹ̀ ọ́ OLUWA, ranti bí mo ti sìn ọ́ pẹlu òtítọ́ ati ọkàn pípé, ati bí mo ti ń ṣe ohun tí o fẹ́.” Ó sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

4. Aisaya jáde kúrò lọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn kí ó tó jáde kúrò ní àgbàlá ààfin, OLUWA sọ fún un pé,

5. “Pada lọ sọ́dọ̀ Hesekaya, olórí àwọn eniyan mi, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀, mo sì ti rí omijé rẹ̀. N óo wò ó sàn, ní ọjọ́ kẹta, yóo lọ sí ilé OLUWA,

6. n óo sì jẹ́ kí ó gbé ọdún mẹẹdogun sí i. N óo gba òun ati Jerusalẹmu lọ́wọ́ ọba Asiria. N óo sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí tèmi fúnra mi ati nítorí ìlérí tí mo ṣe fún Dafidi, iranṣẹ mi.’ ”

7. Aisaya bá sọ fún àwọn iranṣẹ ọba pé kí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ sí orí oówo rẹ̀, kí ara rẹ̀ lè dá.

8. Hesekaya ọba bèèrè pé, “Kí ni yóo jẹ́ àmì pé OLUWA yóo wò mí sàn, ati pé n óo lọ sí ilé OLUWA ní ọjọ́ kẹta?”

9. Aisaya dáhùn pé, “OLUWA yóo fún ọ ní àmì láti fihàn pé òun yóo mú ìlérí òun ṣẹ. Èwo ni o fẹ́, ninu kí òjìji lọ siwaju ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá tabi kí ó pada sẹ́yìn ní ẹsẹ̀ mẹ́wàá?”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 20