Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 16:12-19 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí Ahasi pada dé, o rí i pé Uraya ti mọ pẹpẹ ìrúbọ náà; ó lọ sí ìdí rẹ̀,

13. ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí rẹ̀. Ó rú ẹbọ ohun mímu, ó sì da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ alaafia rẹ̀ sí ara rẹ̀.

14. Pẹpẹ idẹ tí a ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA wà ní ààrin pẹpẹ tirẹ̀ ati ilé OLUWA. Nítorí náà, Ahasi gbé pẹpẹ idẹ náà sí apá òkè pẹpẹ tirẹ̀.

15. Lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún Uraya alufaa, ó ní, “Máa lo pẹpẹ ìrúbọ tí ó tóbi yìí fún ẹbọ sísun àárọ̀ ati ẹbọ ohun jíjẹ ìrọ̀lẹ́, ati fún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọba, ati fún ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu ti àwọn eniyan. Kí o sì máa da ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá pa fún ìrúbọ sí orí rẹ̀. Ṣugbọn gbé pẹpẹ ìrúbọ idẹ tọ̀hún sọ́tọ̀ fún mi kí n lè máa lò ó láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ OLUWA.”

16. Uraya sì ṣe bí Ahasi ọba ti pa á láṣẹ fún un.

17. Ahasi gé àwọn ẹsẹ̀ idẹ ti agbada ńlá, ó gbé agbada náà kúrò. Ó tún gbé agbada omi ńlá tí a fi idẹ ṣe, tí wọ́n gbé ka ẹ̀yìn àwọn akọ mààlúù idẹ mejila, ó sì gbé e lé orí ìpìlẹ̀ tí a fi òkúta ṣe.

18. Nítorí pé Ahasi fẹ́ tẹ́ ọba Asiria lọ́rùn, ó gbé pátákó tí wọ́n tẹ́ fún ìtẹ́ ọba kúrò, ó sì sọ ibẹ̀ dí ẹnu ọ̀nà tí ọba ń gbà wọ ilé OLUWA.

19. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 16