Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 15:30-37 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Ní ogún ọdún tí Jotamu, ọmọ Usaya jọba Juda, ni Hoṣea, ọmọ Ela, dìtẹ̀ mọ́ Peka ọba, ó pa á, ó sì jọba dípò rẹ̀.

31. Gbogbo nǹkan yòókù tí Peka ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

32. Ní ọdún keji tí Peka ọmọ Remalaya, jọba ní Israẹli, ni Jotamu, ọmọ Usaya, jọba ní Juda.

33. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọ Sadoku.

34. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀ sí ọ̀nà Usaya, baba rẹ̀.

35. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run, àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. Òun ni ó kọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìhà àríwá ilé OLUWA.

36. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

37. Ní àkókò tí ó jọba ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí rán Resini, ọba Siria, ati Peka, ọmọ Remalaya, tí í ṣe ọba Israẹli, láti gbógun ti Juda.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 15