Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 14:9-20 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ṣugbọn Jehoaṣi ọba ranṣẹ pada pẹlu òwe yìí: Ó ní, “Ní ìgbà kan ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún kan tí ó wà ní Lẹbanoni ranṣẹ sí igi kedari ní Lẹbanoni pé, ‘Fi ọmọbinrin rẹ fún ọmọkunrin mi ní aya.’ Ṣugbọn ẹranko burúkú kan tí ó wà ní Lẹbanoni ń kọjá lọ, ó sì tẹ ẹ̀gún náà mọ́lẹ̀.

10. Nisinsinyii, ìwọ Amasaya, nítorí pé o ti ṣẹgun Edomu, ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga. Jẹ́ kí ògo rẹ yìí tẹ́ ọ lọ́rùn, kí ló dé tí o fi fẹ́ dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ sí ìparun ara rẹ ati ti Juda?”

11. Ṣugbọn Amasaya kọ̀ kò gbọ́, nítorí náà, Jehoaṣi ọba Israẹli kó ogun lọ pàdé Amasaya ọba Juda ní Beti Ṣemeṣi tí ó wà ní Juda.

12. Israẹli ṣẹgun Juda, gbogbo àwọn ọmọ ogun Juda sì pada sí ilé wọn.

13. Ọwọ́ Jehoaṣi tẹ Amasaya, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Igun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ irinwo igbọnwọ (400 mita).

14. Ó kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí ati gbogbo àwọn ohun èlò ilé OLUWA ati gbogbo ohun tí ó níye lórí ní ààfin, ó sì pada sí Samaria.

15. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe, ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya jà, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

16. Jehoaṣi kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

17. Amasaya ọba, ọmọ Joaṣi gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọba Israẹli.

18. Gbogbo nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

19. Wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amasaya Ọba ní Jerusalẹmu, ó sì sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n rán eniyan lọ bá a níbẹ̀, wọ́n sì pa á.

20. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ sórí ẹṣin wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 14