Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 13:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. OLUWA bínú sí Israẹli, ó sì jẹ́ kí Hasaeli, ọba Siria, ati Benhadadi ọmọ rẹ̀ ṣẹgun Israẹli ní ọpọlọpọ ìgbà.

4. Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀.

5. (Nítorí náà, OLUWA rán olùgbàlà kan sí Israẹli láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Siria, ọkàn àwọn eniyan Israẹli sì balẹ̀ bíi ti ìgbà àtijọ́.

6. Sibẹsibẹ wọn kò yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti mú Israẹli dá. Wọ́n sì tún ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kan náà, ère oriṣa Aṣera sì wà ní Samaria.)

7. Jehoahasi kò ní àwọn ọmọ ogun mọ́ àfi aadọta ẹlẹ́ṣin, ati kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́wàá ati ẹgbaarun (10,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ọba Siria ti pa gbogbo wọn run, ó lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi erùpẹ̀.

8. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoahasi ṣe ati agbára rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

9. Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

10. Ní ọdún kẹtadinlogoji tí Joaṣi jọba ní Juda ni Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun.

11. Òun náà ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀.

12. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya, ọba Juda, jà ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 13