Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 12:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún keje tí Jehu jọba ní Israẹli ni Joaṣi jọba ní ilẹ̀ Juda, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Sibaya tí ó wá láti ìlú Beeriṣeba ni ìyá rẹ̀.

2. Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA nítorí pé Jehoiada alufaa ń tọ́ ọ sọ́nà.

3. Ṣugbọn kò ba àwọn pẹpẹ ìrúbọ jẹ́, àwọn eniyan ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń jó turari.

4. Joaṣi pàṣẹ fún àwọn alufaa pé kí wọ́n máa kó àwọn owó ohun mímọ́ tí wọ́n mú wá sí ilé OLUWA pamọ́: ati gbogbo owó tí àwọn eniyan san fún ẹbọ ìgbà gbogbo ati èyí tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá.

5. Alufaa kọ̀ọ̀kan ni yóo máa tọ́jú owó tí wọ́n bá mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, yóo sì lo owó náà láti máa tún ilé OLUWA ṣe bí ó ti fẹ́.

6. Àwọn alufaa náà kò tún nǹkankan ṣe ninu ilé OLUWA títí tí ó fi di ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi ti jọba.

7. Nítorí náà, ó pe Jehoiada ati àwọn alufaa yòókù, ó bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi tún ilé OLUWA ṣe? Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ gbọdọ̀ máa kó owó tí ẹ bá gbà sílẹ̀ fún àtúnṣe ilé OLUWA.”

8. Àwọn alufaa náà gba ohun tí ọba sọ, wọ́n sì gbà pé àwọn kò ní máa gba owó lọ́wọ́ àwọn eniyan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní tún ilé OLUWA ṣe fúnra wọn.

9. Nígbà náà ni Jehoiada gbé àpótí kan, ó lu ihò sí orí rẹ̀, ó gbé e sí ẹ̀bá pẹpẹ ìrúbọ ní ọwọ́ ọ̀tún tí eniyan bá wọ ilé OLUWA. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA a sì máa kó owó tí àwọn eniyan bá mú wá sinu rẹ̀.

10. Nígbà tí owó bá pọ̀ ninu àpótí náà, akọ̀wé ọba ati olórí Alufaa yóo ka owó náà, wọn yóo sì dì í sinu àpò.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 12