Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 10:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ahabu ní aadọrin ọmọkunrin tí wọn ń gbé Samaria. Jehu kọ ìwé ranṣẹ sí àwọn olórí ìlú ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu, ó ní:

2. “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ọba, ẹ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ẹṣin, ati àwọn ohun ìjà ati àwọn ìlú olódi ní ìkáwọ́ yín. Nítorí náà, ní kété tí ẹ bá gba ìwé yìí,

3. ẹ fi èyí tí ó bá jẹ́ akọni jùlọ lára àwọn ọmọ ọba sí orí oyè, ẹ sì múra láti jà fún ilẹ̀ oluwa yín.”

4. Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ní, “Ǹjẹ́ àwa lè bá Jehu, ẹni tí ó ṣẹgun ọba meji jà?”

5. Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.”

6. Jehu tún kọ ìwé mìíràn sí wọn, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ wà lẹ́yìn mi, ẹ sì ṣetán láti tẹ̀lé àṣẹ mi, ẹ kó orí àwọn ọmọ ọba Ahabu wá fún mi ní Jesireeli ní àkókò yìí ní ọ̀la.”Àwọn aadọrin ọmọ Ahabu náà wà ní abẹ́ ìtọ́jú àwọn àgbààgbà ìlú Samaria.

7. Nígbà tí wọ́n rí ìwé Jehu gbà, àwọn olórí Samaria pa gbogbo àwọn ọmọ Ahabu, wọ́n sì kó orí wọn sinu apẹ̀rẹ̀ lọ fún Jehu ní Jesireeli.

8. Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ fún Jehu pé wọ́n ti kó orí àwọn ọmọ Ahabu dé, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn jọ sí ọ̀nà meji ní ẹnubodè ìlú, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

9. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jehu lọ sí ẹnubodè ìlú, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ pé, “Ẹ kò ní ẹ̀bi, èmi ni mo ṣọ̀tẹ̀ sí Joramu ọba, oluwa mi, tí mo sì pa á. Ṣugbọn ta ni ó pa àwọn wọnyi?

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 10