Jehu tún kọ ìwé mìíràn sí wọn, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ wà lẹ́yìn mi, ẹ sì ṣetán láti tẹ̀lé àṣẹ mi, ẹ kó orí àwọn ọmọ ọba Ahabu wá fún mi ní Jesireeli ní àkókò yìí ní ọ̀la.”Àwọn aadọrin ọmọ Ahabu náà wà ní abẹ́ ìtọ́jú àwọn àgbààgbà ìlú Samaria.