Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 8:21-35 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn.

22. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Israẹli wí fún Gideoni pé, “Máa jọba lórí wa, ìwọ ati ọmọ rẹ, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹlu, nítorí pé ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.”

23. Gideoni dá wọn lóhùn, ó ní “N kò ní jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ mi kò ní jọba lórí yín, OLUWA ni yóo máa jọba lórí yín.”

24. Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n pé kí olukuluku wọn fún òun ní yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀, nítorí pé àwọn ará Midiani a máa lo yẹtí wúrà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilẹ̀ Iṣimaeli yòókù.

25. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A óo fi tayọ̀tayọ̀ kó wọn fún ọ.” Wọ́n bá tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀, olukuluku sì bẹ̀rẹ̀ sí ju yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀ sibẹ.

26. Gbogbo ìwọ̀n yẹtí wúrà tí ó gbà jẹ́ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ṣekeli, láìka ohun ọ̀ṣọ́ ati aṣọ olówó iyebíye tí àwọn ọba Midiani wọ̀, ati àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn àwọn ràkúnmí wọn.

27. Gideoni bá fi wúrà yìí ṣe ère Efodu kan, ó gbé e sí ìlú rẹ̀ ní Ofira, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ ère oriṣa yìí, ó sì di tàkúté fún Gideoni ati ìdílé rẹ̀.

28. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ará Midiani, wọn kò sì lè gbérí mọ́; àwọn ọmọ Israẹli sì sinmi ogun jíjà fún ogoji ọdún, nígbà ayé Gideoni.

29. Gideoni pada sí ilé rẹ̀, ó sì ń gbé ibẹ̀.

30. Aadọrin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ aya.

31. Obinrin rẹ̀ kan tí ń gbè Ṣekemu náà bí ọmọkunrin kan fún un, orúkọ ọmọ yìí ń jẹ́ Abimeleki.

32. Gideoni ọmọ Joaṣi ṣaláìsí lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, wọ́n sin ín sinu ibojì Joaṣi, baba rẹ̀, ní Ofira àwọn ọmọ Abieseri.

33. Bí Gideoni ti ṣaláìsí tán gẹ́rẹ́, àwọn ọmọ Israẹli tún bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali, wọ́n sì sọ Baali-beriti di Ọlọrun wọn.

34. Wọn kò ranti OLUWA Ọlọrun wọn tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo àyíká wọn.

35. Wọn kò ṣe ìdílé Gideoni dáradára bí ó ti tọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san gbogbo nǹkan dáradára tí òun náà ti ṣe fún Israẹli.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 8