Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 8:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Seba ati Salimuna bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ṣugbọn Gideoni lé àwọn ọba Midiani mejeeji yìí títí tí ó fi mú wọn. Jìnnìjìnnì bá dàbo gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn.

13. Ọ̀nà àtigun òkè Heresi ni Gideoni gbà nígbà tí ó ń ti ojú ogun pada bọ̀.

14. Ọwọ́ rẹ̀ tẹ ọdọmọkunrin ará Sukotu kan, ó sì bèèrè orúkọ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà ìlú Sukotu lọ́wọ́ rẹ̀. Ọdọmọkunrin yìí sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkunrin mẹtadinlọgọrin.

15. Ó bá wá sọ́dọ̀ àwọn ọkunrin Sukotu, ó ní, “Ẹ wo Seba ati Salimuna, àwọn ẹni tí ẹ tìtorí wọn pẹ̀gàn mi pé ọwọ́ mi kò tíì tẹ̀ wọ́n, tí ẹ kò sì fún àwọn ọmọ ogun mi tí àárẹ̀ mú ní oúnjẹ. Seba ati Salimuna náà nìyí o.”

16. Ó kó gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú náà, ó sì mú ẹ̀gún ọ̀gàn ati òṣùṣú, ó fi kọ́ wọn lọ́gbọ́n.

17. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Penueli, ó wó ilé ìṣọ́ wọn, ó sì pa àwọn ọkunrin ìlú náà.

18. Lẹ́yìn náà, ó bi Seba ati Salimuna pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí ẹ pa ní Tabori wà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o ti rí gan-an ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn náà rí, gbogbo wọn dàbí ọmọ ọba.”

19. Ó dáhùn, ó ní, “Arakunrin mi ni wọ́n, ìyá kan náà ni ó bí wa. Bí OLUWA ti wà láàyè, bí ó bá jẹ́ pé ẹ dá wọn sí ni, ǹ bá dá ẹ̀yin náà sí.”

20. Ó bá pe Jeteri àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Dìde, kí o sì pa wọ́n,” ṣugbọn ọmọ náà kò fa idà rẹ̀ yọ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á, nítorí ọmọde ni.

21. Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 8