Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 6:21-35 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú.

22. Nígbà náà ni Gideoni tó mọ̀ pé angẹli OLUWA ni, ó bá dáhùn pé, “Yéè! OLUWA Ọlọrun, mo gbé! Nítorí pé mo ti rí angẹli OLUWA lojukooju.”

23. Ṣugbọn OLUWA dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, má bẹ̀rù, o kò ní kú.”

24. Gideoni bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA, ó pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni Alaafia.” Pẹpẹ náà wà ní Ofira ti ìdílé Abieseri títí di òní olónìí.

25. Ní òru ọjọ́ náà, OLUWA sọ fún Gideoni pé, “Mú akọ mààlúù baba rẹ ati akọ mààlúù mìíràn tí ó jẹ́ ọlọ́dún meje, wó pẹpẹ oriṣa Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

26. Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.”

27. Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é.

28. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́.

29. Wọ́n bá ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ló dán irú èyí wò?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti wádìí, wọ́n ní, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.”

30. Àwọn ará ìlú náà bá wí fún Joaṣi pé, “Mú ọmọ rẹ jáde kí á pa á, nítorí pé ó ti wó pẹpẹ oriṣa Baali, ó sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.”

31. Ṣugbọn Joaṣi dá àwọn tí wọ́n dìde sí Gideoni lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ gbèjà oriṣa Baali ni, àbí ẹ fẹ́ dáàbò bò ó? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèjà rẹ̀, pípa ni a óo pa á kí ilẹ̀ tó mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé ọlọrun ni Baali nítòótọ́, kí ó gbèjà ara rẹ̀, nítorí pẹpẹ rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.”

32. Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti ń pe Gideoni ní Jerubaali, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ẹ jẹ́ kí Baali bá a jà fúnra rẹ̀,” nítorí pé ó wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.

33. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Midiani ati àwọn ará ilẹ̀ Amaleki ati àwọn ará ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn kó ara wọn jọ, wọ́n la odò Jọdani kọjá, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí àfonífojì Jesireeli.

34. Ṣugbọn Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Gideoni, Gideoni bá fọn fèrè ogun, àwọn ọmọ Abieseri bá pe ara wọn jáde wọ́n bá tẹ̀lé e.

35. Ó ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Manase, wọ́n pe ara wọn jáde, wọ́n sì tẹ̀lé e. Ó tún ranṣẹ bákan náà sí ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Sebuluni, ati ẹ̀yà Nafutali, àwọn náà sì lọ pàdé rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 6