Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 6:12-18 BIBELI MIMỌ (BM)

12. ni angẹli OLUWA náà yọ sí i, ó sì wí fún un pé, “OLUWA wà pẹlu rẹ, ìwọ akikanju ati alágbára ọkunrin.”

13. Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.”

14. Ṣugbọn OLUWA yipada sí i, ó sì dá a lóhùn pé, “Lọ pẹlu agbára rẹ yìí, kí o sì gba Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani, ṣebí èmi ni mo rán ọ.”

15. Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.”

16. OLUWA dá a lóhùn, ó ní, “N óo wà pẹlu rẹ, o óo sì run àwọn ará Midiani bí ẹni pé, ẹyọ ẹnìkan péré ni wọ́n.”

17. Gideoni tún dáhùn, ó ní, “Bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ OLUWA ni ò ń bá mi sọ̀rọ̀.

18. Jọ̀wọ́, má kúrò níhìn-ín títí tí n óo fi mú ẹ̀bùn mi dé, tí n óo sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.”Angẹli náà dá Gideoni lóhùn, ó ní, “N óo dúró títí tí o óo fi pada dé.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 6