Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 5:9-23 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ àwọn balogun Israẹli,tí wọ́n fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀ láàrin àwọn eniyan.Ẹ fi ìyìn fún OLUWA.

10. Ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jókòó lórí ẹní olówó iyebíye,ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ rìn.

11. Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò,ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA,ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli.Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn.

12. Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora!Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin!Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ,ìwọ ọmọ Abinoamu!

13. Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀,àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀,láti gbógun ti alágbára.

14. Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà,wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ.Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri,àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni.

15. Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá,àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki,wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.

16. Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan?Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.

17. Àwọn ará Gileadi dúró ní ìlà oòrùn odò Jọdani,kí ló dé tí ẹ̀yà Dani fi dúró ní ìdí ọkọ̀ ojú omi?Àwọn ẹ̀yà Aṣeri jókòó létí òkun,wọ́n wà ní ẹsẹ̀ odò.

18. Àwọn ọmọ Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu dójú ikú,bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ Nafutali,wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu ninu pápá, lójú ogun.

19. “Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megidoàwọn ọba wá, wọ́n jagun,wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun,ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó.

20. Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun,àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn,ni wọ́n ti bá Sisera jà.

21. Odò Kiṣoni kó wọn lọ,odò Kiṣoni, tí ó kún àkúnya.Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, máa fi agbára yan lọ.

22. Àwọn ẹṣin sáré dé, pẹlu ariwo pátákò ẹsẹ̀ wọn,wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ kilẹ̀.”

23. Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi,ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀,nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́;wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 5