Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 5:26-31 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,ó na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó he òòlù àwọn alágbẹ̀dẹ,ó kan Sisera mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo;ó fọ́ ọ lórí,ó lù ú ní ẹ̀bá etí,ó sì fọ́ yángá-yángá.

27. Sisera wó, ó ṣubú lulẹ̀,ó nà gbalaja lẹ́sẹ̀ Jaeli,ó wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀.Ibi tí ó wó sí, náà ni ó sì kú sí.

28. Ìyá Sisera ń yọjú láti ojú fèrèsé,ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọ̀nà láti ibi ihò fèrèsé.Ó ní, “Kí ló dé tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó dé?Kí ló dé tí ó fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí á tó gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣintí wọ́n ń wọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀?”

29. Àwọn ọlọ́gbọ́n jùlọ ninu àwọn obinrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ dá a lóhùn,òun náà sì ń wí fún ara rẹ̀ pé,

30. “Ṣebí ìkógun ni wọ́n ń wá, tí wọ́n sì ń pín?Obinrin kan tabi meji fún ọkunrin kọ̀ọ̀kan,ìkógun àwọn aṣọ aláró fún Sisera,ìkógun àwọn aṣọ aláró tí wọ́n dárà sí lára,aṣọ ìborùn aláró meji tí wọ́n dárà sí lára fún èmi náà?”

31. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ṣègbé, OLUWA;ṣugbọn bí oòrùn ti máa ń fi agbára rẹ̀ ràn,bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa tàn.Ilẹ̀ náà sì wà ní alaafia fún ogoji ọdún.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 5