Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 5:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Debora ati Baraki ọmọ Abinoamu bá kọrin ní ọjọ́ náà pé:

2. Ẹ fi ìyìn fún OLUWA,nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli,àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀.

3. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba;ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè;OLUWA ni n óo kọrin sí,n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli.

4. OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri,nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu,ilẹ̀ mì tìtì,omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́,ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀.

5. Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA,àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli.

6. Ní ìgbà ayé Ṣamgari, ọmọ Anati,ati nígbà ayé Jaeli, ọ̀wọ́ èrò kò rin ilẹ̀ yìí mọ́,àwọn arìnrìnàjò sì ń gba ọ̀nà kọ̀rọ̀.

7. Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá,gbogbo ìlú di àkọ̀tì,títí tí ìwọ Debora fi dìde,bí ìyá, ní Israẹli.

8. Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun,ogun bo gbogbo ẹnubodè.Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli,ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀?

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 5