Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 21:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ Israẹli ti búra nígbà tí wọ́n wà ní Misipa pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wa kò ní fi ọmọ rẹ̀ fún ará Bẹnjamini.”

2. Àwọn eniyan bá wá sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó níwájú Ọlọrun títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì sọkún gidigidi.

3. Wọ́n wí pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, tí ó fi jẹ́ pé lónìí ẹ̀yà Israẹli dín kan?”

4. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n tẹ́ pẹpẹ kan, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níbẹ̀.

5. Àwọn ọmọ Israẹli bèèrè pé, “Èwo ninu gbogbo ẹ̀yà Israẹli ni kò wá sí ibi àjọ níwájú OLUWA?” Nítorí pé wọ́n ti ṣe ìbúra tí ó lágbára nípa ẹni tí kò bá wá siwaju OLUWA ní Misipa, wọ́n ní, “Pípa ni a óo pa á.”

6. Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí káàánú àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini arakunrin wọn, wọ́n ní, “Ẹ̀yà Israẹli dín kan lónìí.

7. Báwo ni a óo ṣe rí aya fún àwọn tí ó ṣẹ́kù; nítorí pé a ti fi OLUWA búra pé a kò ní fi àwọn ọmọbinrin wa fún wọn?”

8. Wọ́n bá bèèrè pé, “Ẹ̀yà wo ninu Israẹli ni kò wá siwaju OLUWA ní Misipa?” Wọ́n rí i pé ẹnikẹ́ni kò wá ninu àwọn ará Jabeṣi Gileadi sí àjọ náà.

9. Nítorí pé nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ, ẹnikẹ́ni láti inú àwọn tí ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi kò sí níbẹ̀.

10. Ìjọ eniyan náà bá rán ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn jagunjagun wọn tí wọ́n gbójú jùlọ, wọ́n sì fún wọn láṣẹ pé, “Ẹ lọ fi idà pa gbogbo àwọn tí ń gbé Jabeṣi Gileadi ati obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn.

11. Ohun tí ẹ ó ṣe nìyí: gbogbo ọkunrin wọn ati gbogbo obinrin tí ó bá ti mọ ọkunrin, pípa ni kí ẹ pa wọ́n.”

12. Wọ́n rí irinwo (400) ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin lára àwọn tí wọn ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì kó wọn wá sí àgọ́ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani.

13. Ni ìjọ eniyan bá ranṣẹ sí àwọn ará Bẹnjamini tí wọ́n wà níbi àpáta Rimoni, pé ìjà ti parí, alaafia sì ti dé.

14. Nígbà náà ni àwọn ará Bẹnjamini tó pada wá, àwọn ọmọ Israẹli sì fún wọn ní àwọn obinrin tí wọ́n mú láàyè ninu àwọn obinrin Jabeṣi Gileadi, ṣugbọn àwọn obinrin náà kò kárí wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 21