Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 2:19-23 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ṣugbọn bí aṣiwaju yìí bá ti kú, kíá, wọn a tún ti yipada, wọn a sì tún ti máa ṣe ohun tí ó burú ju ohun tí àwọn baba wọn ti ṣe lọ. Wọn a máa lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọ́n a máa bọ wọ́n, wọn a sì máa foríbalẹ̀ fún wọn. Wọn kì í sì í fi ìṣe wọn ati oríkunkun wọn sílẹ̀.

20. Nítorí náà inú a bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, a sì wí pé, “Àwọn eniyan wọnyi ti da majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba wọn, wọn kò sì fetí sí òfin mi.

21. Láti ìsinsìnyìí lọ n kò ní lé èyíkéyìí, ninu àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù kí Joṣua tó kú, jáde fún wọn.

22. Àwọn ni n óo lò láti wò ó bí àwọn ọmọ Israẹli yóo máa tọ ọ̀nà tí mo là sílẹ̀, bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe.”

23. Nítorí náà, OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀ náà, kò tètè lé wọn jáde bí kò ti fún Joṣua lágbára láti ṣẹgun wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 2