Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 19:26-30 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, obinrin yìí bá lọ wó lulẹ̀ sì ẹnu ọ̀nà baba arúgbó náà níbi tí ọkunrin tí ó mú un wá wà, ó wà níbẹ̀ títí tí ilẹ̀ fi mọ́ kedere.

27. Ọkunrin yìí bá dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ó ṣílẹ̀kùn ilé náà tí ó sì jáde pé kí òun máa lọ, òkú obinrin rẹ̀ ni ó rí, tí ó nà sílẹ̀ gbalaja lẹ́nu ọ̀nà, lẹ́bàá ìlẹ̀kùn, pẹlu ọwọ́ tí ó nà tí ó fẹ́ ṣílẹ̀kùn.

28. Ó pè é pé kí ó dìde kí àwọn máa lọ. Ṣugbọn obinrin yìí kò dá a lóhùn. Ó bá gbé òkú rẹ̀ nílẹ̀, ó gbé e sẹ́yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì lọ sílé rẹ̀.

29. Nígbà tí ó dé ilé, ó mú ọ̀bẹ, ó gé òkú obinrin yìí sí ọ̀nà mejila, ó sì fi wọ́n ranṣẹ sí gbogbo agbègbè Israẹli.

30. Gbogbo àwọn tí wọ́n rí i sì ń wí pé, “A kò rí irú èyí rí láti ọjọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti títí di àkókò yìí, ọ̀rọ̀ náà tó àpérò, ẹ gbìmọ̀ ohun tí a ó ṣe, kí ẹ sì sọ̀rọ̀.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 19