Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 15:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn ará Filistia bá kógun wá sí Juda, wọ́n sì kọlu ìlú Lehi.

10. Àwọn ọkunrin Juda bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi gbógun tì wá?”Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ni a wá mú; ohun tí ó ṣe sí wa ni àwa náà fẹ́ ṣe sí i.”

11. Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.”

12. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A wá láti dì ọ́ tọwọ́ tẹsẹ̀ kí á sì gbé ọ lọ fún àwọn ará Filistia ni.”Samsoni dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin tìkara yín kò ní pa mí.”

13. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà.

14. Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

15. Ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹrun ninu àwọn ará Filistia.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 15