Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 15:5-18 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ó ṣáná sí àwọn ìtùfù náà, ó sì tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀ ninu oko ọkà àwọn ará Filistia. Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí bá tan iná ran gbogbo ìtí ọkà ati àwọn ọkà tí ó wà ní òòró ati gbogbo ọgbà olifi wọn; gbogbo wọn sì jóná ráúráú.

6. Àwọn ará Filistia bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ta ni ó dán irú èyí wò?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni, ọkọ ọmọ ará Timna ni; nítorí pé àna rẹ̀ fi iyawo rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àwọn ará Filistia bá lọ dáná sun iyawo náà ati baba rẹ̀.

7. Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé bí ẹ óo ti ṣe nìyí n óo gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà, n óo fi yín sílẹ̀.”

8. Samsoni pa ọpọlọpọ ninu wọn. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ ń gbé inú ihò àpáta kan tí ó wà ní Etamu.

9. Àwọn ará Filistia bá kógun wá sí Juda, wọ́n sì kọlu ìlú Lehi.

10. Àwọn ọkunrin Juda bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi gbógun tì wá?”Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ni a wá mú; ohun tí ó ṣe sí wa ni àwa náà fẹ́ ṣe sí i.”

11. Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.”

12. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A wá láti dì ọ́ tọwọ́ tẹsẹ̀ kí á sì gbé ọ lọ fún àwọn ará Filistia ni.”Samsoni dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin tìkara yín kò ní pa mí.”

13. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà.

14. Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

15. Ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹrun ninu àwọn ará Filistia.

16. Samsoni bá dáhùn pé,“Páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa wọ́n jọ bí òkítì,Egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa ẹgbẹrun eniyan.”

17. Lẹ́yìn tí ó wí báyìí tán, ó ju egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Ramati Lehi.

18. Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 15