Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 15:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Samsoni dáhùn pé, “Bí mo bá ṣe àwọn ará Filistia ní ibi ní àkókò yìí, n kò ní jẹ̀bi wọn.”

4. Samsoni bá lọ, ó mú ọọdunrun (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàyè, ó wá ìtùfù, ó sì so àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ní ìrù pọ̀ ní meji meji, ó fi ìtùfù sí ààrin ìrù wọn.

5. Ó ṣáná sí àwọn ìtùfù náà, ó sì tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀ ninu oko ọkà àwọn ará Filistia. Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí bá tan iná ran gbogbo ìtí ọkà ati àwọn ọkà tí ó wà ní òòró ati gbogbo ọgbà olifi wọn; gbogbo wọn sì jóná ráúráú.

6. Àwọn ará Filistia bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ta ni ó dán irú èyí wò?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni, ọkọ ọmọ ará Timna ni; nítorí pé àna rẹ̀ fi iyawo rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àwọn ará Filistia bá lọ dáná sun iyawo náà ati baba rẹ̀.

7. Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé bí ẹ óo ti ṣe nìyí n óo gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà, n óo fi yín sílẹ̀.”

8. Samsoni pa ọpọlọpọ ninu wọn. Ó kúrò níbẹ̀, ó sì lọ ń gbé inú ihò àpáta kan tí ó wà ní Etamu.

9. Àwọn ará Filistia bá kógun wá sí Juda, wọ́n sì kọlu ìlú Lehi.

10. Àwọn ọkunrin Juda bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi gbógun tì wá?”Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ni a wá mú; ohun tí ó ṣe sí wa ni àwa náà fẹ́ ṣe sí i.”

11. Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 15