Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 10:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn ará Amoni sì tún kọjá sí òdìkejì odò Jọdani, wọ́n bá àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Bẹnjamini ati ẹ̀yà Manase jà, gbogbo Israẹli patapata ni wọ́n ń pọ́n lójú.

10. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA, wọ́n ní, “A ti sẹ̀ sí ọ, nítorí pé a ti kọ ìwọ Ọlọrun wa sílẹ̀ a sì ń bọ àwọn oriṣa Baali.”

11. OLUWA bá dá àwọn ọmọ Israẹli lóhùn, ó ní, “Ṣebí èmi ni mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati àwọn ara Amori, ati àwọn ará Amoni ati àwọn ará Filistia.

12. Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn.

13. Sibẹsibẹ ẹ tún kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń bọ oriṣa. Nítorí náà n kò ní gbà yín là mọ́.

14. Ẹ lọ bá àwọn oriṣa tí ẹ ti yàn, kí ẹ ké pè wọ́n, kí àwọn náà gbà yín ní ìgbà ìpọ́njú.”

15. Àwọn ọmọ Israẹli bá dá OLUWA lóhùn pé, “A ti dẹ́ṣẹ̀, fi wá ṣe ohun tí ó bá wù ọ́. Jọ̀wọ́, ṣá ti gbà wá kalẹ̀ lónìí ná.”

16. Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli.

17. Àwọn ọmọ ogun Amoni múra ogun, wọ́n pàgọ́ sí Gileadi, àwọn ọmọ ogun Israẹli náà bá kó ara wọn jọ, wọ́n pàgọ́ tiwọn sí Misipa.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 10