Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 10:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA, wọ́n ní, “A ti sẹ̀ sí ọ, nítorí pé a ti kọ ìwọ Ọlọrun wa sílẹ̀ a sì ń bọ àwọn oriṣa Baali.”

11. OLUWA bá dá àwọn ọmọ Israẹli lóhùn, ó ní, “Ṣebí èmi ni mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati àwọn ara Amori, ati àwọn ará Amoni ati àwọn ará Filistia.

12. Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn.

13. Sibẹsibẹ ẹ tún kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń bọ oriṣa. Nítorí náà n kò ní gbà yín là mọ́.

14. Ẹ lọ bá àwọn oriṣa tí ẹ ti yàn, kí ẹ ké pè wọ́n, kí àwọn náà gbà yín ní ìgbà ìpọ́njú.”

15. Àwọn ọmọ Israẹli bá dá OLUWA lóhùn pé, “A ti dẹ́ṣẹ̀, fi wá ṣe ohun tí ó bá wù ọ́. Jọ̀wọ́, ṣá ti gbà wá kalẹ̀ lónìí ná.”

16. Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli.

17. Àwọn ọmọ ogun Amoni múra ogun, wọ́n pàgọ́ sí Gileadi, àwọn ọmọ ogun Israẹli náà bá kó ara wọn jọ, wọ́n pàgọ́ tiwọn sí Misipa.

18. Àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà Gileadi sì bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Ta ni yóo kọ́kọ́ ko àwọn ọmọ ogun Amoni lójú?” Wọ́n ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kò wọ́n lójú ni yóo jẹ́ olórí fún gbogbo àwa ará Gileadi.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 10