Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 1:7-24 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Adonibeseki bá dáhùn pé, “Aadọrin ọba tí mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ wọn, ni wọ́n máa ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tabili mi. Ẹ̀san ohun tí mo ṣe sí wọn ni Ọlọrun ń san fún mi yìí.” Wọ́n bá mú un wá sí Jerusalẹmu, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.

8. Àwọn ọmọ Juda gbógun ti ìlú Jerusalẹmu; wọ́n gbà á, wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbébẹ̀, wọ́n sì sun ún níná.

9. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu.

10. Àwọn ọmọ Juda tún lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ìlú Heburoni, (Kiriati Araba ni orúkọ tí wọn ń pe Heburoni tẹ́lẹ̀); wọ́n ṣẹgun Ṣeṣai, Ahimani ati Talimai.

11. Nígbà tí wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Debiri. (Kiriati Seferi ni orúkọ tí wọ́n ń pe Debiri tẹ́lẹ̀.)

12. Kalebu ní ẹnikẹ́ni tí ó bá gbógun ti ìlú Kiriati Seferi tí ó sì ṣẹgun rẹ̀, ni òun óo fi Akisa, ọmọbinrin òun fún kí ó fi ṣe aya.

13. Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, ṣẹgun ìlú náà, Kalebu bá fi Akisa, ọmọbinrin rẹ̀ fún un kí ó fi ṣe aya.

14. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọrọ pápá ìdaran lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Akisa lọ bá baba rẹ̀, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni baba rẹ̀ bi í pé, “Kí lo fẹ́?”

15. Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀.

16. Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀.

17. Àwọn ọmọ Juda bá àwọn ọmọ Simeoni, arakunrin wọn, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Sefati. Wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n run wọ́n patapata, wọ́n sì sọ ìlú náà ní Horima.

18. Àwọn ọmọ Juda ṣẹgun ìlú Gasa ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀. Wọ́n ṣẹgun ìlú Aṣikeloni ati Ekironi ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè wọn.

19. OLUWA wà pẹlu àwọn ọmọ Juda, ọwọ́ wọn tẹ àwọn ìlú olókè, ṣugbọn apá wọn kò ká àwọn tí ó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn.

20. Wọ́n fún Kalebu ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí, Kalebu sì lé àwọn ọmọ Anaki mẹtẹẹta kúrò níbẹ̀.

21. Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò lé àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu jáde; láti ìgbà náà ni àwọn ará Jebusi ti ń bá àwọn ọmọ Bẹnjamini gbé ní Jerusalẹmu títí di òní olónìí.

22. Àwọn ọmọ Josẹfu náà gbógun ti ìlú Bẹtẹli, OLUWA sì wà pẹlu wọn.

23. Wọ́n rán àwọn amí láti lọ wo Bẹtẹli. (Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀.)

24. Àwọn amí náà rí ọkunrin kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú náà, wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà tí a óo gbà wọ ìlú yìí hàn wá, a óo sì ṣe ọ́ lóore.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 1