Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 8:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ní ọjọ́ náà, n óo mú kí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́kanrí, ilẹ̀ yóo sì ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.

10. N óo yí àsè àjọ̀dún yín pada sí ọ̀fọ̀, n óo sọ orin yín di ẹkún; n óo sán aṣọ ìbànújẹ́ mọ́ gbogbo yín nídìí, n óo sì mú kí orí gbogbo yín pá; ẹ óo dàbí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo, ọjọ́ náà yóo korò ju ewúro lọ.”

11. OLUWA Ọlọrun ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo rán ìyàn sí ilẹ̀ náà; kì í ṣe ìyàn, oúnjẹ, tabi ti omi, ìran láti ọ̀dọ̀ OLUWA ni kò ní sí.

12. Wọn yóo máa lọ káàkiri láti òkun dé òkun, láti ìhà àríwá sí ìhà ìlà oòrùn. Wọn yóo máa sá sókè sódò láti wá ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní rí i.

13. Nígbà tó bá yá, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn wundia yóo dákú nítorí òùngbẹ.

14. Gbogbo àwọn tí wọn ń fi oriṣa Aṣima ti Samaria búra, tí wọn ń wí pé: ‘Bí oriṣa rẹ ti wà láàyè, ìwọ Dani,’ ati, ‘Bí ọ̀nà Beeriṣeba ti wà láàyè;’ gbogbo wọn yóo ṣubú, wọn kò sì ní dìde mọ́.”

Ka pipe ipin Amosi 8