Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 7:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA Ọlọrun fi ìran kan hàn mí! Ó ń kó ọ̀wọ́ eṣú jọ ní àkókò tí koríko ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè, lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ti ọba tán.

2. Nígbà tí àwọn eṣú náà ti jẹ gbogbo koríko ilẹ̀ náà tán, mo ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́ dáríjì àwọn eniyan rẹ. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí pé wọ́n kéré níye?”

3. OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.”

4. OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí Ọlọrun pe iná láti fi jẹ àwọn eniyan rẹ̀ níyà. Iná náà jó ibú omi, ráúráú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ilẹ̀ pàápàá.

5. Nígbà náà ni mo dáhùn pé: “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, dáwọ́ dúró. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí wọ́n kéré níye?”

6. OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.”

Ka pipe ipin Amosi 7