OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí Ọlọrun pe iná láti fi jẹ àwọn eniyan rẹ̀ níyà. Iná náà jó ibú omi, ráúráú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ilẹ̀ pàápàá.