Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 6:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Àwọn tí ń sùn sórí ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe gbé! Àwọn tí wọ́n nà kalẹ̀ lórí ìrọ̀gbọ̀kú wọn, tí wọn ń jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan, ati ti ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù láti inú agbo ẹran wọn!

5. Àwọn tí ń fi hapu kọ orin ìrégbè, tí wọ́n sì ń ṣe ohun èlò orin fún ara wọn bíi Dafidi.

6. Àwọn tí wọn ń fi abọ́ mu ọtí, tí wọn ń fi òróró olówó iyebíye para, ṣugbọn tí wọn kò bìkítà fún ìparun Josẹfu.

7. Nítorí náà, àwọn ni wọn yóo kọ́kọ́ lọ sí ìgbèkùn, gbogbo àsè ati ayẹyẹ àwọn tí wọn ń nà kalẹ̀ sórí ibùsùn yóo dópin.

8. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra, ó ní: “Mo kórìíra ìwà ìgbéraga Jakọbu, ati gbogbo àwọn ibi ààbò rẹ̀; n óo mú ọwọ́ kúrò lọ́rọ̀ ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”

9. Bí ó bá ku eniyan mẹ́wàá ninu ìdílé kan, gbogbo wọn yóo kú.

10. Nígbà tí ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìsìnkú bá kó eegun òkú jáde, tí ó bá bi àwọn eniyan tí ó kù ninu ilé pé, “Ǹjẹ́ ó ku ẹnikẹ́ni mọ́?”Wọn yóo dá a lóhùn pé, “Rárá.”Nígbà náà ni olùdarí ìsìnkú yóo sọ pé, “Ẹ dákẹ́, ẹ ṣọ́ra, a kò gbọdọ̀ tilẹ̀ dárúkọ OLUWA.”

11. Wò ó! OLUWA pàṣẹ pé, a óo wó àwọn ilé ńlá, ati àwọn ilé kéékèèké lulẹ̀ patapata.

12. Ṣé ẹṣin a máa sáré lórí àpáta? Àbí eniyan a máa fi àjàgà mààlúù pa ilẹ̀ lórí òkun? Ṣugbọn ẹ ti sọ ẹ̀tọ́ di májèlé, ẹ sì ti sọ èso òdodo di ohun kíkorò.

13. Ẹ fọ́nnu pé ẹ̀yin ni ẹ ṣẹgun ìlú Lodebari, ẹ̀ ń wí pé: “Ṣebí agbára wa ni a fi gba ìlú Kanaimu.”

14. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, n óo rán orílẹ̀-èdè kan láti pọn yín lójú, wọn yóo sì fìyà jẹ yín láti ibodè Hamati, títí dé odò Araba.”

Ka pipe ipin Amosi 6