Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 2:11-16 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Mo yan àwọn kan ninu àwọn ọmọ yín ní wolii mi, mo sì yan àwọn mìíràn ninu wọn ní Nasiri. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

12. Ṣugbọn ẹ̀ ń mú kí àwọn Nasiri mu ọtí, ẹ sì ń dá àwọn wolii mi lẹ́kun, pé wọn kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́.

13. Wò ó, n óo tẹ̀ yín ní àtẹ̀rẹ́ ní ibùgbé yín, bí ìgbà tí ọkọ̀ kọjá lórí eniyan.

14. Ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ yóo mú àwọn tí wọ́n lè sáré; ipá àwọn alágbára yóo pin, akikanju kò sì ní lè gba ara rẹ̀ sílẹ̀.

15. Tafàtafà kò ní lè dúró, ẹni tí ó lè sáré kò ní lè sá àsálà; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣin kò ní lè gba ara wọn kalẹ̀.

16. Ìhòòhò ni àwọn akọni láàrin àwọn ọmọ ogun yóo sálọ ní ọjọ́ náà.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Amosi 2