Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 9:16-21 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni,àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun.

17. Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn,àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe énítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun,ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

18. Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná,tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn.Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.

19. Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná,àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu ináẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí.

20. Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́,sibẹ ebi ń pa wọ́n.Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì,sibẹ wọn kò yó,àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ.

21. Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà.Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

Ka pipe ipin Aisaya 9