Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 8:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún mi pé, “Mú ìwé kan tí ó fẹ̀, kí o kọ Maheriṣalali-haṣi-basi sí i lórí gàdàgbà gàdàgbà.”

2. Mo bá pe Alufaa Uraya ati Sakaraya, ọmọ Jebẹrẹkaya, kí wọn wá ṣe ẹlẹ́rìí mi nítorí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

3. Nígbà tí mo bá iyawo mi, tí òun náà jẹ́ wolii lò pọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin. OLUWA bá sọ fún mi pé kí n sọ ọmọ náà ní Maheriṣalali-haṣi-basi.

4. Nítorí kí ọmọ náà tó mọ bí a tí ń pe ‘Baba mi’ tabi ‘Mama mi’, wọn óo ti kó àwọn nǹkan alumọni Damasku ati ìkógun Samaria lọ sí Asiria.

5. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀ ó ní,

6. “Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi kọ omi Ṣiloa tí ń ṣàn wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sílẹ̀, wọ́n wá ń gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Resini ati ọmọ Remalaya,

7. nítorí náà, ẹ wò ó, OLUWA yóo gbé ọba Asiria ati gbogbo ògo rẹ̀ dìde wá bá wọn, yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí omi odò Yufurate, tí ó kún àkúnya, tí ó sì kọjá bèbè rẹ̀.

8. Yóo ya wọ Juda, yóo sì bò ó mọ́lẹ̀ bí ó ti ń ṣàn kọjá lọ, títí yóo fi mù ún dé ọrùn. Yóo ya wọ inú ilẹ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀; yóo sì bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀. Kí Ọlọrun wà pẹlu wa.”

Ka pipe ipin Aisaya 8