Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 7:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.

15. Nígbà tí yóo bá fi mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú, tí a sì í yan nǹkan rere, wàrà ati oyin ni àwọn eniyan yóo máa jẹ.

16. Nítorí pé kí ọmọ náà tó mọ bí a ti í kọ nǹkan burúkú tí a sì í yan nǹkan rere, ilẹ̀ àwọn ọba mejeeji tí wọn ń bà ọ́ lẹ́rù yìí yóo ti di ìkọ̀sílẹ̀.

17. “OLUWA yóo mú ọjọ́ burúkú dé bá ìwọ ati àwọn eniyan rẹ ati ilé baba rẹ, ọjọ́ tí kò ì tíì sí irú rẹ̀ rí, láti ìgbà tí Efuraimu ti ya kúrò lára Juda, OLUWA ń mú ọba Asiria bọ̀.

18. “Ní ọjọ́ náà OLUWA yóo súfèé pe àwọn eṣinṣin tí ó wà ní orísun gbogbo odò Ijipti ati àwọn oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Asiria.

19. Gbogbo wọn yóo sì rọ́ wá sí ààrin àwọn àfonífojì, ati gbogbo kọ̀rọ̀ kọ̀rọ̀ ní ààrin àpáta, ati ara gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún ati gbogbo pápá.

20. “Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo mú ọba Asiria wá láti òdìkejì odò. Yóo lò ó bí abẹ ìfárí, yóo fi fá irun orí ati irun ẹsẹ̀ dànù, ati gbogbo irùngbọ̀n pàápàá.

21. “Ní ọjọ́ náà, eniyan yóo máa sin ẹyọ mààlúù kékeré kan ati aguntan meji péré,

22. wàrà tí yóo máa rí fún yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé wàrà ati oyin ni yóo máa fi ṣe oúnjẹ jẹ. Nítorí pé wàrà ati oyin ni àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà yóo máa jẹ.

23. “Ní ọjọ́ náà, gbogbo ibi tí ẹgbẹrun ìtàkùn àjàrà wà, tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹrun ṣekeli fadaka, yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn.

24. Àwọn eniyan yóo kó ọrun ati ọfà wá sibẹ, nítorí gbogbo ilẹ̀ náà yóo di igbó ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn.

25. Gbogbo ara òkè tí wọn tí ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní lè débẹ̀ mọ́, nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀wọ̀n agogo ati ẹ̀gún ọ̀gàn, gbogbo ibẹ̀ yóo wá di ibi tí mààlúù ati aguntan yóo ti máa jẹko.”

Ka pipe ipin Aisaya 7