Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 66:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ta ló gbọ́ irú èyí rí?Ta ló rí irú rẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan,tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan?Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí,ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin.

9. Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí,kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí?Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ,ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?”

10. Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀,ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀.

11. Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu;kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú,ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.

12. Nítorí OLUWA ní:“N óo tú ibukun sórí rẹ̀,bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn.N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè.Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú,ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀.

13. N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún,bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu.

14. Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí,bí ìgbà tí koríko bá rúwé.Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀,ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

15. Wò ó! OLUWA ń bọ̀ ninu iná,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo dàbí ìjì,láti fi ìrúnú san ẹ̀san,yóo sì fi ahọ́n iná báni wí.

16. Nítorí pé iná ni OLUWA yóo fi ṣe ìdájọ́,idà ni yóo fi ṣe ìdájọ́ fún gbogbo eniyan;àwọn tí OLUWA yóo fi idà pa yóo sì pọ̀.

17. OLUWA ní, “Àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ń lọ bọ̀rìṣà ninu àgbàlá, wọ́n ń jó ijó oriṣa, wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀, ati àwọn ohun ìríra, ati èkúté! Gbogbo wọn ni yóo ṣègbé papọ̀.

18. Nítorí mo mọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn ati èrò ọkàn wọn. Mò ń bọ̀ wá gbá gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà jọ. Nígbà tí wọ́n bá dé, wọ́n óo rí ògo mi.

19. “N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

Ka pipe ipin Aisaya 66