Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 66:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Èmi náà óo sì yan ìjìyà fún wọn,n óo jẹ́ kí ẹ̀rù wọn pada sórí wọn.Nítorí pé nígbà tí mo pè wọ́n, ẹnikẹ́ni wọn kò dáhùn;nígbà tí mo sọ̀rọ̀ fún wọn, wọn kò gbọ́,wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú mi,wọ́n yan ohun tí inú mi kò dùn sí.”

5. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀:“Àwọn arakunrin yín tí wọn kórìíra yín,wọ́n tì yín síta nítorí orúkọ mi;wọ́n ní, ‘Jẹ́ kí OLUWA fi ògo rẹ̀ hàn,kí á lè rí ayọ̀ yín.’Ṣugbọn àwọn ni ojú yóo tì.

6. Ẹ gbọ́ ariwo ninu ìlú,ẹ gbọ́ ohùn kan láti inú Tẹmpili,ohùn OLUWA ni,ó ń san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

7. “Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ.Kí ìrora obí tó mú un,ó ti bí ọmọkunrin kan.

8. Ta ló gbọ́ irú èyí rí?Ta ló rí irú rẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan,tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan?Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí,ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin.

9. Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí,kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí?Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ,ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?”

10. Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀,ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀.

11. Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu;kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú,ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.

12. Nítorí OLUWA ní:“N óo tú ibukun sórí rẹ̀,bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn.N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè.Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú,ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀.

13. N óo rẹ̀ yín lẹ́kún bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rẹ̀ lẹ́kún,bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tù yín ninu ní Jerusalẹmu.

14. Ẹ óo rí i, inú yín yóo dùn, egungun yín yóo sọjí,bí ìgbà tí koríko bá rúwé.Gbogbo eniyan yóo sì mọ̀ pé ọwọ́ OLUWA wà lára àwọn iranṣẹ rẹ̀,ati pé inú bí i sí àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

Ka pipe ipin Aisaya 66