Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 63:13-19 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀;wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ.

14. Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù,Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi.Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀,kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀.

15. Bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,láti ibùgbé rẹ mímọ́ tí ó lógo.Ìtara rẹ dà? Agbára rẹ dà?O ti dáwọ́ ìfẹ́ ati àánú rẹ dúró lára wa ni?

16. Ìwọ ni baba wa.Bí Abrahamu kò tilẹ̀ mọ̀ wá,tí Israẹli kò sì dá wa mọ̀.Ìwọ OLUWA ni baba wa,Olùràpadà wa láti ìgbà àtijọ́, ni orúkọ rẹ.

17. OLUWA kí ló dé tí o fi jẹ́ kí á ṣìnà, kúrò lọ́dọ̀ rẹ;tí o sé ọkàn wa lé, tí a kò fi bẹ̀rù rẹ?Pada sọ́dọ̀ wa nítorí àwọn iranṣẹ rẹ,nítorí àwọn ẹ̀yà Israẹli tíí ṣe ìní rẹ.

18. Fún ìgbà díẹ̀, ilé mímọ́ rẹ jẹ́ ti àwa eniyan mímọ́ rẹ;ṣugbọn àwọn ọ̀tá wa ti wó o lulẹ̀.

19. A wá dàbí àwọn tí o kò jọba lórí wọn rí,àní, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè.

Ka pipe ipin Aisaya 63