Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 62:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Bí ọdọmọkunrin tií nífẹ̀ẹ́ wundia,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkunrin rẹ yóo nífẹ̀ẹ́ rẹ.Bí inú ọkọ iyawo tuntun tíí dùn nítorí iyawo rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun rẹ yóo dùn nítorí rẹ.

6. Jerusalẹmu, mo ti fi àwọn aṣọ́de sí orí odi rẹ;lojoojumọ, tọ̀sán-tòru, wọn kò gbọdọ̀ panumọ́.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rán OLUWA létí,ẹ má dákẹ́.

7. Ẹ má jẹ́ kí ó sinmi,títí yóo fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀,títí yóo fi sọ ọ́ di ìlú ìyìn láàrin gbogbo ayé.

8. OLUWA ti fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ búra,ó ti fi agbára rẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́,pé òun kò ní fi ọkà oko rẹ,ṣe oúnjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ mọ́;àwọn àjèjì kò sì ní mu ọtí waini rẹ,tí o ṣe wahala lé lórí mọ́.

9. Ṣugbọn àwọn tí ó bá gbin ọkà, ni yóo máa jẹ ẹ́,wọn óo sì máa fìyìn fún OLUWA;àwọn tí ó bá sì kórè àjàrà ni yóo mu ọtí rẹ̀,ninu àgbàlá ilé mímọ́ mi.

10. Ẹ kọjá! Ẹ gba ẹnubodè kọjá,ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn eniyan.Ẹ la ọ̀nà, ẹ la òpópónà,kí ẹ ṣa òkúta kúrò níbẹ̀.Ẹ ta àsíá sókè, fún àwọn eniyan náà.

11. Wò ó! OLUWA ti kéde títí dé òpin ayé.Ó ní, “Ẹ sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,‘Wò ó, olùgbàlà yín ti dé,èrè rẹ wà pẹlu rẹ̀,ẹ̀san rẹ sì wà níwájú rẹ̀.’ ”

12. A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”,“Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”.Wọn óo máa pè yín ní,“Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”;wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní,“Ìlú tí a kò patì”.

Ka pipe ipin Aisaya 62