Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 57:5-11 BIBELI MIMỌ (BM)

5. ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku,ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì,ati ní abẹ́ àpáta?

6. Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì,àwọn ni ẹ̀ ń sìn,àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí,àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí.Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?

7. Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ síníbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.

8. O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn.O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀.O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀,ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.

9. O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki,o kó ọpọlọpọ turari lọ,o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.

10. Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà,sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.”Ò ń wá agbára kún agbára,nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.

11. Ta ni ń já ọ láyà,tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́;tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi?Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́,ni o kò fi bẹ̀rù mi?

Ka pipe ipin Aisaya 57