Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 57:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Olódodo ń ṣègbé,kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i.A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé,pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.

2. Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia,wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn.

3. Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi,ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́,ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga.

4. Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sítí ẹ yọ ṣùtì sí?Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yínirú ọmọ ẹ̀tàn;

5. ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku,ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì,ati ní abẹ́ àpáta?

6. Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì,àwọn ni ẹ̀ ń sìn,àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí,àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí.Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?

7. Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ síníbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.

Ka pipe ipin Aisaya 57