Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 54:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ.Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀,ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ,OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

2. Fẹ ààyè àgọ́ rẹ sẹ́yìn,sì jẹ́ kí aṣọ tí ó ta sórí ibùgbé rẹ gbòòrò sí i, má ṣẹ́wọ́ kù.Na okùn àgọ́ rẹ kí ó gùn,kí o sì kan èèkàn rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ó lágbára.

3. Nítorí o óo tàn kálẹ̀, sí apá ọ̀tún ati apá òsì,àwọn ọmọ rẹ yóo gba ìtẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè,wọn óo sì máa gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro.

4. Má bẹ̀rù nítorí ojú kò ní tì ọ́,má sì dààmú, nítorí a kì yóo dójú tì ọ́,nítorí o óo gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ,o kò sì ní ranti ẹ̀sín ìgbà tí o jẹ́ opó mọ́.

5. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ,OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ,Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.

6. Nítorí OLUWA ti pè ọ́,bí iyawo tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́,àní, bí iyawo àárọ̀ ẹni, tí a kọ̀ sílẹ̀;OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

7. Mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀,ṣugbọn n óo kó ọ jọ pẹlu ọpọlọpọ àánú.

8. Mo fojú mi pamọ́ fún ọ,fún ìgbà díẹ̀ nítorí inú mi ń ru sí ọ,ṣugbọn nítorí ìfẹ́ àìlópin mi, n óo ṣàánú fún ọ.Èmi OLUWA, Olùràpadà rẹ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi:mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii,pé n kò ní bínú sí ọ mọ́,pé n kò ní bá ọ wí mọ́.

Ka pipe ipin Aisaya 54