Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 51:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sáré ìdáǹdè,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá OLUWA,ẹ wo àpáta tí a mú lára rẹ̀, tí a fi gbẹ yín,ati kòtò ibi tí a ti wà yín jáde.

2. Ẹ wo Abrahamu baba yín,ati Sara tí ó bi yín.Òun nìkan ni nígbà tí mo pè é,tí mo súre fún un,tí mo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ eniyan.

3. “OLUWA yóo tu Sioni ninu,yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu;yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA.Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀,pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀.

4. “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi,ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde,ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan.

5. Ìdáǹdè mi súnmọ́ tòsí,ìgbàlà mi sì ti ń yọ bọ̀.Èmi ni n óo máa ṣe àkóso àwọn eniyan,àwọn erékùṣù yóo gbẹ́kẹ̀lé mi,ìrànlọ́wọ́ mi ni wọn yóo sì máa retí.

6. Ẹ gbójú sókè, ẹ wo ojú ọ̀run,kí ẹ sì wo ayé ní ìsàlẹ̀.Ọ̀run yóo parẹ́ bí èéfín,ayé yóo gbó bí aṣọ,àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ yóo sì kú bíi kòkòrò;ṣugbọn títí lae ni ìgbàlà mi,ìdáǹdè mi kò sì ní lópin.

7. “Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi,ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan;ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà.

8. Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ,kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú;ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae,ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.”

Ka pipe ipin Aisaya 51