Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 5:28-30 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Ọfà wọn mú wọ́n kẹ́ ọrun wọn.Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin wọn le bí òkúta akọ;ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn dàbí ìjì líle.

29. Bíbú wọn dàbí ti kinniun,wọn a bú ramúramù bí ọmọ kinniun,wọn a kígbe, wọn a sì ki ohun ọdẹ wọn mọ́lẹ̀,wọn a gbé e lọ, láìsí ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ wọn.

30. Wọn óo hó lé Israẹli lórí lọ́jọ́ náàbí ìgbà tí omi òkun ń hó.Bí eniyan bá wọ ilẹ̀ náà yóo rí òkùnkùn ati ìnira.Ìkùukùu rẹ̀ yóo sì bo ìmọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 5