Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 5:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi,kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kanní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá.

2. Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò.Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀.Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀,ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ.Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so,ṣugbọn èso kíkan ni ó so.

3. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda,mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi.

4. Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe?Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn,kí ló dé tí ó fi so èso kíkan?

5. Nisinsinyii n óo sọ ohun tí n óo ṣe sí ọgbà àjàrà mi fun yín.N óo tú ọgbà tí mo ṣe yí i ká,iná yóo sì jó o.N óo wó odi tí mo mọ yí i ká,wọn yóo sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.

6. N óo jẹ́ kí ó di igbó,ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́,wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́.Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀.N óo pàṣẹ fún òjòkí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́.

7. Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun,àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀.Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan;ó ń retí ìwà òdodo,ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe.

8. Ègbé ni fún àwọn tí ó ń kọ́lé mọ́lé,tí wọn ń gba ilẹ̀ kún ilẹ̀,títí tí kò fi sí ilẹ̀ mọ́,kí ẹ̀yin nìkan baà lè máa gbé ilẹ̀ náà.

9. OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní,“Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro,ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé.

Ka pipe ipin Aisaya 5