Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 5:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ jẹ́ kí n kọrin kan fún olùfẹ́ mi,kí n kọrin nípa ọgbà àjàrà rẹ̀.Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kanní orí òkè kan tí ilẹ̀ ibẹ̀ lọ́ràá.

2. Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò.Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀.Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀,ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ.Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so,ṣugbọn èso kíkan ni ó so.

3. Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ati ẹ̀yin ará Juda,mo bẹ̀ yín, ẹ wá ṣe ìdájọ́ láàrin èmi ati ọgbà àjàrà mi.

4. Kí ló tún kù tí ó yẹ kí n ṣe sí ọgbà àjàrà mi tí n kò ṣe?Ìgbà tí mo retí kí ó so èso dídùn,kí ló dé tí ó fi so èso kíkan?

Ka pipe ipin Aisaya 5