Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 49:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ilẹ̀ etí òkun.Ẹ fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ará ilẹ̀ òkèèrè,láti inú oyún ni OLUWA ti pè mí,láti inú ìyá mi wá ni ó ti dárúkọ mi.

2. Ó ṣe ẹnu mi bí idà mímú,ó fi mí pamọ́ sí ibi òjìji ọwọ́ rẹ̀,ó ṣe mí ní ọfà tí ó mú,ó fi mí pamọ́ sinu apó rẹ̀.

3. Ó sọ fún mi pé, “Iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli,àwọn eniyan óo máa yìn mí lógo nítorí rẹ.”

4. Ṣugbọn mo dáhùn pé,“Mo ti ṣiṣẹ́ àṣedànù.Mo ti lo agbára mi ṣòfò, mo ti fi ṣe àṣedànù,sibẹsibẹ ẹ̀tọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ OLUWA.”Ẹ̀san mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọrun mi, yóo san án fún mi.

5. Nisinsinyii, OLUWA, tí ó ṣẹ̀dá mi ninu oyún,kí n lè jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, láti mú Jakọbu pada tọ̀ ọ́ wá,ati láti mú kí Israẹli kórajọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀; nítorí mo níyì lójú OLUWA,Ọlọrun mi sì ti di agbára mi.

6. OLUWA ní nǹkan kékeré ni kí n jẹ́ iranṣẹ òun,láti gbé àwọn ẹ̀yà Jakọbu dìde, ati láti kó àwọn ọmọ Israẹli tí ó kù jọ.Ó ní òun óo fi mí ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdèkí ìgbàlà òun lè dé òpin ayé.

7. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ,fún ẹni tí ayé ń gàn,tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra,iranṣẹ àwọn aláṣẹ,ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde,àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀.Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo,Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”

8. OLUWA ní,“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo dá ọ lóhùn,lọ́jọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.Mo ti pa ọ́ mọ́,mo sì ti fi ọ́ dá majẹmu pẹlu àwọn aráyé,láti fìdí ilẹ̀ náà múlẹ̀,láti pín ilẹ̀ tí ó ti di ahoro.

9. Kí o máa sọ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé, ‘Ẹ jáde,’ati fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn pé, ‘Ẹ farahàn.’Wọn óo rí ohun jíjẹ ní gbogbo ọ̀nà,gbogbo orí òkè yóo sì jẹ́ ibùjẹ fún wọn.

10. Ebi kò ní pa wọ́n,òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n,atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n,nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn,yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn.

11. “N óo sọ gbogbo òkè mi di ojú ọ̀nà,n óo kún gbogbo òpópó ọ̀nà mi.

12. Wò ó! Òkèèrè ni èyí yóo ti wá,láti àríwá ati láti ìwọ̀ oòrùn, àní láti ilẹ̀ Sinimu.”

13. Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀,ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin,nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ.

14. Sioni ń wí pé,“OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀,Oluwa mi ti gbàgbé mi.”

15. OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú?Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀?Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé.Èmi kò ní gbàgbé rẹ.

Ka pipe ipin Aisaya 49